1 John 4:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
A mọ ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa, a sì ní igbagbọ ninu ìfẹ́ yìí. Ìfẹ́ ni Ọlọrun. Ẹni tí ó bá ń gbé inú ìfẹ́ ń gbé inú Ọlọrun, Ọlọrun náà sì ń gbé inú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́. Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́ ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀.