1 John 5:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọrun gbọ́ ní ẹ̀rí yìí ninu ara rẹ̀. Ẹni tí kò bá gba Ọlọrun gbọ́ mú Ọlọrun lékèé, nítorí kò gba ẹ̀rí tí Ọlọrun ti jẹ́ nípa Ọmọ rẹ̀ gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti o ba gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́, o ni ẹrí ninu ara rẹ̀: ẹniti kò ba gbà Ọlọrun gbọ́, o ti mu u li eke; nitori kò gbà ẹrí na gbọ́ ti Ọlọrun jẹ niti Ọmọ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀; ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké; nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀.