1 Kings 1:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Natani bá tọ Batiṣeba ìyá Solomoni lọ, ó bi í pé, “Ṣé o ti gbọ́ pé Adonija ọmọ Hagiti ti fi ara rẹ̀ jọba, Dafidi ọba kò sì mọ nǹkankan nípa rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Natani si wi fun Batṣeba, iya Solomoni pe, Iwọ kò gbọ́ pe, Adonijah, omọ Haggiti jọba, Dafidi, oluwa wa, kò si mọ̀?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Nátanì bèrè lọ́wọ́ Bátíṣébà, ìyá Sólómọ́nì pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kò gbọ́ pé Àdóníjà, ọmọ Hágítì ti jọba láìjẹ́ pé Dáfídì OLÚWA wa mọ̀ síi?