1 Kings 1:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Tọ Dafidi ọba lọ lẹsẹkẹsẹ, kí o sì bi í pé, ṣebí òun ni ó fi ìbúra ṣe ìlérí fún ọ pé Solomoni ọmọ rẹ ni yóo jọba lẹ́yìn rẹ̀? Kí ló dé tí Adonija fi di ọba?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lọ, ki o si tọ̀ Dafidi, ọba lọ, ki o si wi fun u pe, Ọba, oluwa mi, ṣe iwọ li o bura fun ọmọ-ọdọ rẹ obinrin, pe, nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, ni yio jọba lẹhin mi, on ni o si joko lori itẹ mi? ẽṣe ti Adonijah fi jọba?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ọba, kí o sì wí fún un pé, ‘OLÚWA mi ọba, ǹjẹ́ ìwọ kò búra fún ìránṣẹ́ rẹ pé, “Dájúdájú Sólómónì ọmọ rẹ ni yóò Jọba lẹ́yìn mi, yóò sì jókòó lórí ìtẹ́ mi?” Èéṣe nígbà náà tí Àdóníjà fi jọba?’