1 Kings 1:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ti fi ọpọlọpọ akọ mààlúù, ati aguntan, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ. Ó pe gbogbo àwọn ọmọ ọba lọkunrin, ati Abiatari alufaa, ati Joabu balogun rẹ síbi àsè rẹ̀, ṣugbọn kò pe Solomoni, iranṣẹ rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si pa malu ati ẹran ti o li ọra, ati agùtan li ọ̀pọlọpọ, o si pe gbogbo awọn ọmọ ọba, ati Abiatari alufa, ati Joabu balogun: ṣugbọn Solomoni iranṣẹ rẹ ni kò pè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun sì ti fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ màlúù, àti ẹran tí ó ní ọ̀rá, àti àgùntàn rúbọ, ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba, àti Ábíátarì àlùfáà àti Jóábù balógun, ṣùgbọ́n kò sì pe Sólómónì ìránṣẹ́ rẹ.