1 Kings 1:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá ọdọmọbinrin tí ó lẹ́wà gidigidi ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli. Wọ́n rí ọdọmọbinrin arẹwà kan ní ìlú Ṣunemu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abiṣagi, wọ́n sì mú un tọ Dafidi wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wá ọmọbinrin arẹwà kan ka gbogbo agbegbe Israeli, nwọn si ri Abiṣagi, ara Ṣunemu, nwọn si mu u tọ̀ ọba wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni wọ́n lọ jákèjádo ilẹ̀ Ísírẹ́lì láti wá ọ̀dọ́mọbìnrin arẹwà, wọ́n sì rí Ábíságì, ará Ṣúnémù, wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ ọba.