1 Kings 1:41 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí Adonija ati gbogbo àwọn tí ó pè sí ibi àsè rẹ̀ ti ń parí àsè, wọ́n gbọ́ ariwo náà. Nígbà tí Joabu gbọ́ fèrè, ó bèèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ gbogbo ariwo tí wọn ń pa ninu ìlú yìí?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Adonijah ati gbogbo awọn ti o pè sọdọ rẹ̀ si gbọ́, nigbati nwọn jẹun tan, Joabu si gbọ́ iró ipè o si wipe: eredi ariwo ilu ti nrọkẹkẹ yi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àdóníjà àti gbogbo awọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ ọ́ bí wọ́n ti ń jẹun tán, wọ́n ń gbọ́ ipè, Jóábù sì wí pé, “Kí ní ìtumọ̀ gbogbo ariwo nínú ìlú yìí?”