1 Kings 1:44 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó sì ti rán Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba pé kí wọ́n tẹ̀lé Solomoni, wọ́n sì ti gbé e gun orí ìbaaka ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si ti rán Sadoku alufa, ati Natani woli, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati awọn ara Kereti ati Peleti pẹlu rẹ̀, nwọn si ti mu u ki o gùn ibãka ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì ti rán Sádókù àlùfáà, Nátanì wòlíì, Bénáyà ọmọ Jéhóíádà àti àwọn ará Kérétì àti Pélétì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ti gbé e gun ìbaka ọba,