1 Kings 1:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Adonija, ọmọ tí Hagiti bí fún Dafidi, bẹ̀rẹ̀ sí gbéraga, ó ń wí pé, “Èmi ni n óo jọba.” Ó bá lọ tọ́jú kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati aadọta ọkunrin tí yóo máa sáré níwájú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Adonijah, ọmọ Haggiti, si gbe ara rẹ̀ ga, wipe, emi ni yio jọba: o si mura kẹkẹ́ ati awọn ẹlẹṣin, ati ãdọta ọkunrin lati sare niwaju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àdóníjà ẹni tí ìyá rẹ̀ ń ṣe Hágátì sì gbé ara rẹ̀ ga, ó sì wí pé, “Èmi yóò jẹ ọba.” Ó sì sètò kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin, pẹ̀lú àádọ́ta ọkùnrin láti máa sáré níwájú rẹ̀.