1 Kings 1:53 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni ọba bá ranṣẹ lọ mú Adonija wá láti ibi pẹpẹ. Adonija lọ siwaju ọba, ó sì wólẹ̀. Ọba sọ fún un pé kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni ọba si ranṣẹ, nwọn mu u sọkalẹ lori pẹpẹ. On si wá, o si foribalẹ̀ fun Solomoni ọba: Solomoni si wi fun u pe, Mã lọ ile rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Sólómónì ọba rán àwọn ènìyàn, wọ́n sì mú un sọ̀kalẹ̀ láti ibi pẹpẹ wá. Àdóníjà sì wá, ó sì foríbalẹ̀ fún Sólómónì ọba, Sólómónì sì wí pé, “Lọ ilé rẹ.”