1 Kings 1:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan, Adonija fi ọpọlọpọ aguntan, pẹlu akọ mààlúù, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ níbi Àpáta Ejò, lẹ́bàá orísun Enrogeli, ó sì pe àwọn ọmọ ọba yòókù, àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní ilẹ̀ Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Adonijah si pa agutan ati malu ati ẹran ọ̀sin ti o sanra nibi okuta Soheleti, ti mbẹ lẹba Enrogeli, o si pè gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ ọba, ati gbogbo ọkunrin Juda, iranṣẹ ọba:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Àdóníjà fi àgùntàn àti màlúù àti ẹran ọ̀sìn tí ó sanra rúbọ níbi òkúta Sóhélétì tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Énrógélì. Ó sì pe gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ ọba, àti gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ ọba.