1 Kings 10:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni ọba fi igi alimugi náà ṣe òpó ilé OLUWA ati ti ààfin rẹ̀. Ó tún lò ninu wọn, ó fi ṣe ohun èlò orin tí wọ́n ń pè ní hapu ati gòjé fún àwọn akọrin rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò rí irú igi alimugi bẹ́ẹ̀ mọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí di òní olónìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si fi igi Algumu na ṣe opó fun ile Oluwa, ati fun ile ọba dùru pẹlu ati ohun-elo orin miran fun awọn akọrin: iru igi Algumu bẹ̃ kò de mọ, bẹ̃ni a kò ri wọn titi di oni yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì fi igi Álúgúmù náà ṣe òpó fún ilé OLÚWA àti fún ààfin ọba, àti láti ṣe dùùrù pẹ̀lú àti ohun èlò orin mìíràn fún àwọn akọrin. Irú igi Álúgúmù bẹ́ẹ̀ kò dé mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí wọn títí di òní yìí.