1 Kings 10:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ohun tí ọbabinrin Ṣeba fẹ́, tí ó tọrọ lọ́wọ́ Solomoni pátá ni Solomoni fún un, láìka ọpọlọpọ ẹ̀bùn tí wọ́n ti kọ́ fi ṣe é lálejò. Ọbabinrin náà pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá pada sí ilẹ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba ni gbogbo ifẹ rẹ̀, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti a fi fun u lati ọwọ Solomoni ọba wá. Bẹ̃li o si yipada, o si lọ si ilu rẹ̀, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì ọba sì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tí ó béèrè, yàtọ̀ sí èyí tí a fi fún un láti ọwọ́ Sólómónì ọba wa. Nígbà náà ni ó yípadà, ó sì lọ sí ìlú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.