1 Kings 10:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
láìka èyí tí àwọn oníṣòwò ń san fún un, èyí tí ń wá láti ibi òwò rẹ̀, ati èyí tí àwọn ọba Arabia ati àwọn gomina ilẹ̀ Israẹli ń san.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Laika eyi ti o ngbà lọwọ awọn ajẹlẹ ati awọn oniṣowo, ati ti gbogbo awọn ọba Arabia, ati ti awọn bãlẹ ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Árábíà, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀.