1 Kings 10:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó kó ọpọlọpọ iranṣẹ lẹ́yìn, ó sì di turari olóòórùn dídùn, pẹlu òkúta olówó iyebíye ati ọpọlọpọ wúrà ru ọpọlọpọ ràkúnmí; ó wá sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ patapata fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wá si Jerusalemu pẹlu ẹgbẹ nlanla, ibakasiẹ ti o ru turari, ati ọ̀pọlọpọ wura, ati okuta oniyebiye: nigbati o si de ọdọ Solomoni o ba a sọ gbogbo eyiti mbẹ li ọkàn rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wá sí Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ràkúnmí tí ó ru tùràrí, ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Sólómónì, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀.