1 Kings 10:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wúrà ni wọ́n fi ṣe gbogbo ife ìmumi Solomoni, ati gbogbo àwọn ohun èlò tí ó wà ninu Ilé Igbó Lẹbanoni. Kò sí ẹyọ kan ninu wọn tí wọ́n fi fadaka ṣe, nítorí pé fadaka kò já mọ́ nǹkankan ní àkókò Solomoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo ohun-elo mimu Solomoni ọba jẹ wura, ati gbogbo ohun-elo ile igbo Lebanoni jẹ wura daradara; kò si fadaka; a kò kà a si nkankan li ọjọ Solomoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo ohun èlò mímu Sólómónì ọba sì jẹ́ wúrà àti gbogbo ohun èlò ààfin igbó Lébánónì sì jẹ́ kìkì wúrà. Kò sí ìkankan tí a fi fàdákà ṣe, nítorí a kò ka fàdákà sí nǹkankan ní gbogbo ọjọ́ Sólómónì.