1 Kings 10:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi tí wọ́n máa ń bá àwọn ọkọ̀ ojú omi Hiramu lọ sí òkè òkun. Ọdún kẹta kẹta ni wọ́n máa ń pada dé, wọn á sì máa kó ọpọlọpọ wúrà, ati fadaka, eyín erin, ìnàkí, ati ẹyẹ ọ̀kín bọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ọba ni ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹlu ọkọ̀ Hiramu li okun: ẹ̃kan li ọdun mẹta li ọkọ̀ Tarṣiṣi idé, ti imu wura ati fadaka, ehin-erin ati inakí ati ẹiyẹ-ologe wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì ní ọkọ̀ Tásísì kan pẹ̀lú ọkọ̀ Hírámù ní òkun. Ẹ̀ẹ̀kan ní ọdún mẹ́ta ni ọkọ̀ Tásísì ń dé, tí ó ń mú wúrà àti fàdákà, eyín-erin àti ìnàkí àti ẹyẹ-ológe wá.