1 Kings 10:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdọọdún ni ọpọlọpọ eniyan máa ń mú ọpọlọpọ ẹ̀bùn àwọn nǹkan tí wọ́n fi fadaka ati wúrà ṣe wá sọ́dọ̀ rẹ̀, pẹlu ẹ̀wù, ati turari olóòórùn dídùn, ẹṣin, ati ìbaaka.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olukuluku nwọn si mu ọrẹ tirẹ̀ wá, ohun-elo fadaka, ati ohun-elo wura, ati ẹ̀wu, ati turari, ẹṣin ati ibãka, iye kan lọdọdun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún olúkúlùkù àwọn tí ń wá sì ń mú ẹ̀bùn tirẹ̀ wá, ohun èlò fàdákà àti ohun èlò wúrà àti ẹ̀wù, àti tùràrí olóòórùn dídùn, ẹṣin àti ìbááka.