1 Kings 10:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọpọlọpọ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹlẹ́ṣin ni Solomoni ọba kó jọ, kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ jẹ́ egbeje (1,400), àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ sì jẹ́ ẹgbaafa (1,200). Ó fi apá kan ninu wọn sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn yòókù sí ìlú ńláńlá tí ó ń kó àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sí káàkiri.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni si ko kẹkẹ́ ati èṣin jọ: o si ni egbeje kẹkẹ́ ati ẹgbãfa ẹlẹsin, o si fi wọn si ilu kẹkẹ́, ati pẹlu ọba ni Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì sì kó kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jọ; ó sì ní egbèje (1400) kẹ̀kẹ́ àti ẹgbàata (13,000) ẹlẹ́ṣin, tí ó fi pamọ́ sí ìlú kẹ̀kẹ́ àti pẹ̀lú rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù.