1 Kings 10:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka ni wọ́n máa ń ra kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn oníṣòwò Solomoni níí máa ń tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati àwọn ọba ilẹ̀ Siria.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kẹkẹ́ kan ngoke o si njade lati Egipti wá fun ẹgbẹta ṣekeli fadakà, ati ẹṣin kan fun ãdọjọ: bẹ̃ni nwọn si nmu wá pẹlu nipa ọwọ wọn fun gbogbo awọn ọba awọn ọmọ Hiti ati fun awọn ọba Siria.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ń mú kẹ̀kẹ́ kan gòkè láti Éjíbítì wá fún ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì fàdákà àti ẹsin kan fún àádọ́jọ (150). Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún mú wọn wá fún ọba àwọn ọmọ Hítì àti ọba àwọn ọmọ Árámánì.