1 Kings 10:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
irú oúnjẹ tí ó wà lórí tabili rẹ̀, ìjókòó àwọn ìjòyè rẹ̀, ìṣesí àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ìwọṣọ wọn, àwọn tí wọ́n ń gbé ọtí rẹ̀ ati ẹbọ sísun tí ó ń rú ninu ilé OLUWA, ẹnu yà á lọpọlọpọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati iwọṣọ wọn, ati awọn agbọti rẹ̀, ati ọna ti o mba goke lọ si ile Oluwa; kò kù agbara kan fun u mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Oúnjẹ tí ó wà lórí i tábìlì rẹ̀, ìjókòó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti ìdúró àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti ìwọṣọ wọn, àwọn agbọ́tí rẹ̀, àti ẹbọ ọrẹ̀ sísun tí ó sun ní ilé OLÚWA, kò sì sí ẹ̀mí kan nínú rẹ̀ mọ́!