1 Kings 10:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn n kò gbàgbọ́ títí tí mo fi wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Àwọn tí wọ́n sọ fún mi kò tilẹ̀ sọ ìdajì ohun tí mo rí. Ọgbọ́n, ati ọrọ̀ rẹ pọ̀ rékọjá ohun tí mo gbọ́ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ na gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri: si kiyesi i, a kò sọ idajì wọn fun mi: iwọ si ti fi ọgbọ́n ati irọra kún okiki ti mo gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n èmi kò sì gba nǹkan wọ̀nyí gbọ́ títí ìgbà tí mo wá, tí mo sì fi ojú ara mi rí i. Sì kíyèsí i, a kò sọ ìdajì wọn fún mi; ìwọ sì ti fi ọgbọ́n àti ìrora kọjá òkìkí tí mo gbọ́.