1 Kings 10:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ, ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí ọ, tí ó sì fi ọ́ jọba Israẹli. Nítorí ìfẹ́ ayérayé tí ó ní sí Israẹli ni ó ṣe fi ọ́ jọba lórí wọn, kí o lè máa ṣe ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ati ti òdodo.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o ni inu-didùn si ọ lati gbe ọ ka ori itẹ́ Israeli: nitoriti Oluwa fẹràn Israeli titi lai, nitorina li o ṣe fi ọ jọba, lati ṣe idajọ ati otitọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìbùkún ni fún OLÚWA Ọlọ́run rẹ, tí ó ní inú dídùn sí ọ, tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ Ísírẹ́lì. Nítorí tí OLÚWA fẹ́ràn Ísírẹ́lì títí láé, ni ó ṣe fi ọ́ jọba, láti ṣe ìdájọ́ àti òdodo.”