1 Kings 11:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọpọlọpọ àwọn obinrin àjèjì ni Solomoni fẹ́, lẹ́yìn ọmọ Farao, ọba Ijipti, tí ó kọ́kọ́ fẹ́, ó tún fẹ́ ará Moabu ati ará Amoni, ará Edomu ati ará Sidoni, ati ará Hiti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
ṢUGBỌN Solomoni ọba fẹràn ọ̀pọ ajeji obinrin, pẹlu ọmọbinrin Farao, awọn obinrin ara Moabu, ti Ammoni, ti Edomu, ti Sidoni ati ti awọn ọmọ Hitti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sólómónì ọba fẹ́ ọ̀pọ̀ àjèjì obìnrin yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò, àwọn ọmọbìnrin Móábù, àti ti Ámónì, ti Édómù, ti Sídónì àti ti àwọn ọmọ Hítì.