1 Kings 11:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Adadi ati àwọn iranṣẹ baba rẹ̀ wọnyi kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Ní Parani yìí ni àwọn ọkunrin mìíràn ti para pọ̀ mọ́ wọn, tí gbogbo wọ́n sì jọ lọ sí Ijipti. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Farao, ọba Ijipti, ó fún Adadi ní ilé ati ilẹ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún un déédé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si dide kuro ni Midiani, nwọn si wá si Parani; nwọn si mu enia pẹlu wọn lati Parani wá: nwọn si wá si Egipti, sọdọ Farao ọba Egipti, o si fun u ni ile kan, o si yàn onjẹ fun u, o si fun u ni ilẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì dìde kúrò ní Mídíánì, wọ́n sì lọ sí Páránì. Nígbà náà ni wọ́n mú ènìyàn pẹ̀lú wọn láti Páránì wá, wọ́n sì lọ sí Éjíbítì, sọ́dọ̀ Fáráò ọba Éjíbítì ẹni tí ó fún Hádádì ní ilé àti ilẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ.