1 Kings 11:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni ọba fẹ́ wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli tẹ́lẹ̀, pé wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ fi ọmọ fún wọn; kí àwọn orílẹ̀-èdè náà má baà mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli ṣí sọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn orilẹ-ède ti Oluwa wi fun awọn ọmọ-Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ wọle tọ̀ wọn, bẹ̃ni awọn kò gbọdọ wọle tọ̀ nyin: nitõtọ nwọn o yi nyin li ọkàn pada si oriṣa wọn: Solomoni fà mọ awọn wọnyi ni ifẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n wá láti orílẹ̀ èdè tí OLÚWA ti wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fẹ́ wọn níyàwó tàbí ní ọkọ, nítorí wọn yóò yí ọkàn yín padà sí òrìṣà wọn.” Síbẹ̀ síbẹ̀ Sólómónì fà mọ́ wọn ní ìfẹ́.