1 Kings 11:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Arabinrin ayaba Tapenesi yìí bí ọmọkunrin kan fún Adadi, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Genubati. Inú ilé Farao ọba ni ayaba Tapenesi ti tọ́ ọmọ náà dàgbà, láàrin àwọn ọmọ ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Arabinrin Tapenesi si bi Genubati ọmọ rẹ̀ fun u, Tapenesi si já a li ẹnu ọmu ni ile Farao: Genubati si wà ni ile Farao lãrin awọn ọmọ Farao,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Arábìnrin Tápénésì bí ọmọkùnrin kan fún un tí à ń pe orúkọ rẹ̀ ní Génúbátì, ẹni tí Tápénésì tọ́ dàgbà ní ààfin ọba. Níbẹ̀ ni Génúbátì ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ Fáráò fún ra rẹ̀.