1 Kings 11:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Adadi gbọ́ ní Ijipti pé Dafidi ọba ti kú, ati pé Joabu, balogun rẹ̀ náà ti kú, ó wí fún Farao pé, “Jẹ́ kí n pada lọ sí ìlú mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Hadadi si gbọ́ ni Egipti pe, Dafidi sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ati pe Joabu olori-ogun si kú, Hadadi si wi fun Farao pe, rán mi lọ, ki emi ki o le lọ si ilu mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó sì wà ní Éjíbítì, Hádádì sì gbọ́ pé Dáfídì ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àti pé Jóábù olórí ogun sì ti kú pẹ̀lú. Nígbà náà ni Hádádì wí fún Fáráò pé, “Jẹ́ kí n lọ, kí èmi kí ó le padà sí ìlú mi.”