1 Kings 11:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun Hadadeseri ọba, tí ó sì ti pa àwọn ará Siria tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, Resoni di olórí àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan tí wọ́n kó ara wọn jọ, tí wọn ń gbé Damasku. Àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá fi jọba ní Damasku.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si ko enia jọ sọdọ ara rẹ̀, o si di olori-ogun ẹgbẹ́ kan, nigbati Dafidi fi pa wọn, nwọn si lọ si Damasku, nwọn ngbe ibẹ, nwọn si jọba ni Damasku.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì kó ènìyàn jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí ogun ẹgbẹ́ kan, nígbà tí Dáfídì fi pa ogun Sóbà run; wọ́n sì lọ sí Dámásíkù, wọ́n ń gbé ibẹ̀, wọ́n sì jọba ní Dámásíkù.