1 Kings 11:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó ṣe akiyesi Jeroboamu pé ó jẹ́ ọdọmọkunrin tí ó ní akitiyan. Nígbà tí Solomoni rí i bí ó ti ń ṣiṣẹ́ kára kára, ó fi ṣe olórí àwọn tí wọn ń kóni ṣiṣẹ́ tipátipá ní gbogbo agbègbè ẹ̀yà Manase ati Efuraimu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin na, Jeroboamu, ṣe alagbara akọni: nigbati Solomoni si ri ọdọmọkunrin na pe, oṣiṣẹ enia ni, o fi i ṣe olori gbogbo iṣẹ-iru ile Josefu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jéróbóámù jẹ́ ọkùnrin alágbára, nígbà tí Sólómónì sì rí bí ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ dáradára, ó fi í ṣe olórí iṣẹ́ ìrú ilé Jóṣẹ́fù.