1 Kings 11:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kan, Jeroboamu ń ti Jerusalẹmu lọ sí ìrìn àjò kan, wolii Ahija, láti Ṣilo sì pàdé òun nìkan lójú ọ̀nà, ninu pápá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe li àkoko na, nigbati Jeroboamu jade kuro ni Jerusalemu, woli Ahijah ara Ṣilo ri i loju ọ̀na; o si wọ̀ agbáda titun; awọn meji pere li o si mbẹ ni oko:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì ṣe, ní àkókò náà Jéróbóámù ń jáde kúrò ní Jérúsálẹ́mù. Wòlíì Áhíjà ti Ṣílò sì pàdé rẹ̀ lójú ọ̀nà, ó sì wọ agbádá túntún. Àwọn méjèèjì nìkan ni ó sì ń bẹ ní oko,