1 Kings 11:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn yóo ku ẹ̀yà kan sí ọwọ́ Solomoni, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ati nítorí Jerusalẹmu, ìlú tí òun yàn fún ara òun ninu gbogbo ilẹ̀ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn on o ni ẹya kan nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jérúsálẹ́mù, ìlú tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, òun yóò ní ẹ̀yà kan.