1 Kings 11:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé, Solomoni ti kọ òun sílẹ̀, ó sì ń bọ Aṣitoreti, oriṣa àwọn ará Sidoni; ati Kemoṣi, oriṣa àwọn ará Moabu; ati Milikomu oriṣa àwọn ará Amoni. Solomoni kò máa rìn ní ọ̀nà òun OLUWA, kí ó máa ṣe rere, kí ó máa pa òfin òun mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé ìlànà òun bí Dafidi baba rẹ̀ ti ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si mbọ Astoreti, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Kemoṣi, oriṣa awọn ara Moabu, ati Milkomu, oriṣa awọn ọmọ Ammoni, nwọn kò si rin li ọ̀na mi, lati ṣe eyiti o tọ́ li oju mi, ati lati pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò ṣe èyí nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti sin Ásítórétì òrìṣà àwọn ará Sídónì, Kémósì òrìṣà àwọn ará Móábù, àti Mííkámù òrìṣà àwọn ọmọ Ámónì, wọn kò sì rìn ní ọ̀nà mi, tàbí ṣe èyí tí ó dára lójú mi, tàbí pa àṣẹ àti òfin mi mọ́ bí Dáfídì bàbá Sólómónì ti ṣe.