1 Kings 11:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sibẹsibẹ ó ní òun kò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ Solomoni, òun óo fi sílẹ̀ láti máa ṣe ìjọba ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí ti Dafidi, iranṣẹ òun, ẹni tí òun yàn, tí ó pa òfin òun mọ́, tí ó sì tẹ̀lé ìlànà òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi kì yio gba gbogbo ijọba na lọwọ rẹ̀, ṣugbọn emi o ṣe e li ọmọ-alade ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, nitori Dafidi, iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn, nitori o ti pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣùgbọ́n èmi kì yóò gba gbogbo ìjọba náà lọ́wọ́ Sólómónì; èmi ti mú un jẹ́ olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ nítorí ti Dáfídì ìránṣẹ́ mi, ẹni tí mo yàn, tí ó sì ti pa òfin mi àti àṣẹ mi mọ́.