1 Kings 11:38 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Tí o bá fetí sí gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ fún ọ, tí o sì ń rìn ní ọ̀nà òun, tí ò ń ṣe ohun tí ó tọ́ lójú òun, tí o pa òfin òun mọ́ tí o sì ń mú àṣẹ òun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, iranṣẹ òun ti ṣe, ó ní òun óo wà pẹlu rẹ, arọmọdọmọ rẹ ni yóo máa jọba lẹ́yìn rẹ, òun óo fi ìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ bí òun ti ṣe fún Dafidi; òun óo sì fi Israẹli fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, bi iwọ o ba tẹtisilẹ si gbogbo eyiti mo paṣẹ fun ọ, ti iwọ o mã rin li ọ̀na mi, ti iwọ o si mã ṣe eyiti o tọ́ loju mi, lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi iranṣẹ mi ti ṣe; emi o si wà pẹlu rẹ, emi o si kọ́ ile otitọ fun ọ, gẹgẹ bi emi ti kọ́ fun Dafidi, emi o si fi Israeli fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìwọ bá ṣe gbogbo èyí tí mo pàṣẹ fún ọ, tí o sì rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú mi nípa pípa òfin àti àṣẹ mi mọ́, bí i Dáfídì ìránṣẹ́ mi ti ṣe, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò kọ́ ilé òtítọ́ fún ọ bí èyí tí mo kọ́ fún Dáfídì, èmi yóò sì fi Ísírẹ́lì fún ọ.