1 Kings 12:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ohun tí o óo wí fún àwọn tí wọ́n ní baba rẹ di ẹrù wúwo lé àwọn lórí, ṣugbọn kí o bá àwọn dín ẹrù yìí kù ni pé ìka ọwọ́ rẹ tí ó kéré jùlọ tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba rẹ lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ipẹrẹ ti o dagba pẹlu rẹ̀ wi fun u pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn enia yi ti nwọn ba ọ sọ wipe, Baba rẹ mu ki àjaga wa di wuwo, sugbọn iwọ mu ki o fuyẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o sọ fun wọn: ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọdé tí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Sọ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n wí fún ọ pé, ‘Baba rẹ̀ mú kí àjàgà wa wúwo ṣùgbọ́n ìwọ mú kí ó fúyẹ́ díẹ̀ fún wa’; sọ fún wọn pé, ìka ọwọ́ mi kékeré nípọn ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ.