1 Kings 12:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
gẹ́gẹ́ bí àwọn ọdọmọkunrin ti gbà á nímọ̀ràn. Ó ní, “Ẹrù wúwo ni ẹ sọ pé baba mi dì rù yín, ṣugbọn èmi yóo tilẹ̀ tún dì kún un ni. Ẹgba ni ó fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si sọ fun wọn gẹgẹ bi ìmọran awọn ipẹrẹ wipe, Baba mi mu ki àjaga nyin ki o wuwo, emi o si bù kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọmọdé, ó sì wí pé, “Baba mí sọ àjàgà yín di wúwo; Èmi yóò sì jẹ́ kí ó wúwo sí i; Baba mi fi pàsán nà yín; Èmi yóò fí àkéekèe nà yín.”