1 Kings 12:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé, ọba kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dá a lóhùn pé, “Kí ló kàn wá pẹlu ìdílé Dafidi? Kí ló dà wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese? Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ pada sílé yín, kí Dafidi máa bojútó ilé rẹ̀!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kò fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba li ohùn wipe: Ipin kini awa ni ninu Dafidi? bẹ̃ni awa kò ni iní ninu ọmọ Jesse: Israeli, ẹ pada si agọ nyin: njẹ mã bojuto ile rẹ, Dafidi! Bẹ̃ni Israeli pada sinu agọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé: ìpín wo ni àwa ní nínú Dáfídì, Ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jésè? Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì! Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dáfídì! Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Ísírẹ́lì padà sí ilé wọn.