1 Kings 12:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Rehoboamu ọba rán Adoniramu, tí ó jẹ́ ọ̀gá àgbà àwọn tí wọn ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́ tipátipá, láti lọ bá àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Rehoboamu bá múra kíá, ó bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá lọ sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Rehoboamu ọba, ran Adoramu ẹniti iṣe olori iṣẹ-iru; gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Nitorina Rehoboamu, ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀, lati sá lọ si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Réhóbóámù ọba rán Ádórámù jáde, ẹni tí ń ṣe olórí iṣẹ́ irú, ṣùgbọ́n gbogbo Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa, Réhóbóámù ọba, yára láti gun kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó sì sá lọ sí Jérúsálẹ́mù.