1 Kings 12:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé Jeroboamu ti pada dé láti ilẹ̀ Ijipti, wọ́n pè é sí ibi ìpàdé kan tí wọ́n ṣe, wọ́n sì fi jọba Israẹli. Kò sí ẹni tí ó tẹ̀lé ìdílé Dafidi, àfi ẹ̀yà Juda nìkan ṣoṣo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe nigbati gbogbo Israeli gbọ́ pe Jeroboamu tun pada bọ̀, ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pè e wá si ajọ, nwọn si fi i jọba lori gbogbo Israeli: kò si ẹnikan ti o tọ̀ ile Dafidi lẹhin, bikoṣe kiki ẹya Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì sì gbọ́ pé Jéróbóámù ti padà dé, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì pè é wá sí àjọ, wọ́n sì fi jẹ ọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì. Kò sí ẹnìkan tí ó tọ ilé Dáfídì lẹ́yìn bí kò ṣe kìkì ẹ̀yà Júdà nìkan.