1 Kings 12:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Rehoboamu pada dé Jerusalẹmu, ó ṣa ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) ọmọ ogun tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ láti inú ẹ̀yà Juda ati ti Bẹnjamini, láti lọ gbógun ti ilé Israẹli kí wọ́n sì gba ìjọba ìhà àríwá Israẹli pada fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Rehoboamu si wá si Jerusalemu, o ko gbogbo ile Juda jọ, pẹlu ẹya Benjamini, ọkẹ mẹsan enia ti a yàn, ti nwọn iṣe ologun, lati ba ile Israeli ja, lati mu ijọba na pada bọ̀ sọdọ Rehoboamu, ọmọ Solomoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Réhóbóámù sì dé sí Jérúsálẹ́mù, ó kó gbogbo ilé Júdà jọ, àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì; ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Ísírẹ́lì jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Réhóbóámù, ọmọ Sólómónì.