1 Kings 12:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
pé OLUWA ni wọn kò gbọdọ̀ gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé arakunrin wọn ni wọ́n, ati pé kí olukuluku pada sí ilé rẹ̀, nítorí pé ìfẹ́ òun Ọlọrun ni ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Nítorí náà gbogbo wọ́n gba ohun tí OLUWA pa láṣẹ, wọ́n sì pada sí ilé wọn bí OLUWA ti wí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi, Ẹnyin kò gbọdọ goke bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ba awọn arakunrin nyin jà: ẹ pada olukuluku si ile rẹ̀; nitori nkan yi ati ọdọ mi wá ni. Nwọn si gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, nwọn si pada lati lọ, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Báyìí ni OLÚWA wí: Ẹ má ṣe gòkè lọ láti bá àwọn arákùnrin yín jà, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì. Ẹ padà, olúkúlùkù yín sí ilé rẹ̀, nítorí nǹkan yìí láti ọ̀dọ̀ mi wá ni.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA, wọ́n sì tún padà sí ilé wọn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLÚWA.