1 Kings 12:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “Bí àwọn eniyan wọnyi bá ń lọ rúbọ ní ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, ọkàn gbogbo wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ pada sẹ́yìn Rehoboamu, oluwa wọn; wọn óo sì pa mí, wọn óo sì pada tọ Rehoboamu, ọba Juda, lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn enia wọnyi ba ngoke lọ lati ṣe irubọ ni ile Oluwa ni Jerusalemu, nigbana li ọkàn awọn enia yi yio tun yipada sọdọ oluwa wọn, ani sọdọ Rehoboamu, ọba Juda, nwọn o si pa mi, nwọn o si tun pada tọ̀ Rehoboamu, ọba Juda lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí bá gòkè lọ láti ṣe ìrúbọ ní ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù, wọn yóò tún fi ọkàn wọn fún OLÚWA wọn, Réhóbóámù ọba Júdà. Wọn yóò sì pa mí, wọn yóò sì tún padà tọ Réhóbóámù ọba Júdà lọ.”