1 Kings 12:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jeroboamu lọ gba àmọ̀ràn, ó bá fi wúrà yá ère akọ mààlúù meji, ó sì wí fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ó pẹ́ tí ẹ ti ń lọ rúbọ ní Jerusalẹmu. Ó tó gẹ́ẹ́! Ọlọrun yín, tí ó ko yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti nìyí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si gbìmọ, o si ya ẹgbọ̀rọ malu wura meji, o si wi fun wọn pe, O pọ̀ju fun nyin lati mã goke lọ si Jerusalemu: Israeli, wò awọn ọlọrun rẹ, ti o mu ọ lati ilẹ Egipti wá!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn tí ó ti gba ìmọ̀ràn, ọba sì yá ẹgbọ̀rọ̀ màlúù wúrà méjì. Ó sì wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ó ti pọ̀jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù. Àwọn Ọlọ́run yín nìyìí, Ísírẹ́lì, tí ó mú yín láti ilẹ̀ Éjíbítì wá.”