1 Kings 12:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jeroboamu ya ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹjọ sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún, gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún ilẹ̀ Juda, ó sì rúbọ lórí pẹpẹ sí akọ mààlúù tí ó fi wúrà ṣe ní ìlú Bẹtẹli. Ó fi àwọn alufaa kan sibẹ, láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa ninu àwọn ilé ìsìn tí ó kọ́ sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jeroboamu si dá àse silẹ li oṣu kẹjọ, li ọjọ Kẹdogun oṣu, gẹgẹ bi àse ti o wà ni Juda, o si gun ori pẹpẹ na lọ: bẹ̃ni o si ṣe ni Beteli, o rubọ si awọn ọmọ-malu ti o ṣe: o si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti o ti ṣe si Beteli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì dá àṣè sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹjọ gẹ́gẹ́ bí àṣè tí ó wà ní Júdà, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ. Ó ṣe èyí ní Bétélì, ó rú ẹbọ sí àwọn ọmọ màlúù tí ó ṣe. Ó sì fi àwọn àlùfáà sí ibi gíga tí ó ti ṣe sí Bétélì.