1 Kings 12:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹjọ tíí ṣe ọjọ́ tí ó yàn fún ara rẹ̀, ó lọ sí ibi pẹpẹ tí ó kọ́ sí ìlú Bẹtẹli láti rúbọ. Ó yan àjọ̀dún fún àwọn ọmọ Israẹli, ó sì lọ sun turari lórí pẹpẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si gun ori pẹpẹ na lọ ti o ti ṣe ni Beteli li ọjọ kẹdogun oṣu kẹjọ, li oṣu ti o rò li ọkàn ara rẹ̀; o si da àse silẹ fun awọn ọmọ Israeli; o si gun ori pẹpẹ na lọ, lati fi turari jona.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kẹjọ, oṣù tí ó rò ní ọkàn ara rẹ̀, ó sì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí ó kọ́ ní Bétélì. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dá àsè sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì gun orí pẹpẹ náà lọ láti rú ẹbọ.