1 Kings 12:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jíròrò pẹlu àwọn ọdọmọkunrin, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọ́n wà ní ààfin pẹlu rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn o kọ̀ ìmọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá, o si ba awọn ipẹrẹ ti nwọn dagba pẹlu rẹ̀, ti nwọn si duro niwaju rẹ̀ gbimọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Réhóbóámù kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un, ó sì fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn ọmọdé tí wọ́n dàgbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọ́n sì ń sìn ín.