1 Kings 13:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wolii àgbàlagbà kan wà ní ìlú Bẹtẹli ní ìgbà náà. Àwọn ọmọ wolii náà lọ sọ ohun tí wolii tí ó wá láti Juda ṣe ní Bẹtẹli ní ọjọ́ náà fún baba wọn, ati ohun tí ó sọ fún Jeroboamu ọba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Woli àgba kan si ngbe Beteli: ọmọ rẹ̀ de, o si rohin gbogbo iṣẹ ti enia Ọlọrun na ti ṣe li ọjọ na ni Beteli fun u: ọ̀rọ ti o sọ fun ọba nwọn si sọ fun baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wòlíì àgbà kan wà tí ń gbé Bétélì, ẹni tí àwọn ọmọ rẹ̀ dé, tí ó sì ròyìn gbogbo ohun tí ènìyàn Ọlọ́run náà ti ṣe ní Béttélì ní ọjọ́ náà fún un. Wọ́n sì tún sọ fún baba wọn ohun tí ó sọ fún ọba.