1 Kings 13:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wolii àgbàlagbà, ará Bẹtẹli náà bá purọ́ fún un pé, “Wolii bíi rẹ ni èmi náà. OLUWA ni ó sì pàṣẹ fún angẹli kan tí ó sọ fún mi pé kí n mú ọ lọ sí ilé, kí n sì fún ọ ní oúnjẹ ati omi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun u pe, Woli li emi pẹlu gẹgẹ bi iwọ; angeli si sọ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Mu u ba ọ pada sinu ile rẹ, ki o le jẹ onjẹ ki o si le mu omi. Ṣugbọn o purọ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wòlíì àgbà náà sì wí fún un pé, “Wòlíì ni èmi náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìwọ. Ańgẹ́lì sì sọ fún mi nípa ọ̀rọ̀ OLÚWA pé: ‘Mú un padà wá sí ilé rẹ, kí ó lè jẹ oúnjẹ àti kí ó lè mu omi.’ ” (Ṣùgbọ́n ó purọ́ fún un ni.)