1 Kings 13:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wolii náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ sí pẹpẹ náà, ó ní, “Ìwọ pẹpẹ yìí, ìwọ pẹpẹ yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ó ní, ‘Wò ó! A óo bí ọmọ kan ninu ìdílé Dafidi, orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́ Josaya. Lórí ìwọ pẹpẹ yìí ni yóo ti fi àwọn alufaa oriṣa tí ń sun turari lórí rẹ rúbọ. A óo sì máa sun egungun eniyan lórí rẹ.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kigbe si pẹpẹ na nipa ọ̀rọ Oluwa, o si wipe, Pẹpẹ! pẹpẹ! bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, a o bi ọmọ kan ni ile Dafidi, Josiah li orukọ rẹ̀; lori rẹ ni yio si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti nfi turari jona lori rẹ rubọ, a o si sun egungun enia lori rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ OLÚWA wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni OLÚWA wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jòsíàh ní ilé Dáfídì. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga yìí tí ó ń mú ọrẹ wá síbẹ̀, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ”